Agbébọn gbẹ̀mí èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún lásìkò tí wọn jí màálù lọ

Awọn ọdẹ ibilẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O kere tan, awọn ọdẹ ibilẹ to le ni ọgọrun ti padanu ẹmi wọn sọwọ awọn agbebọn ni opin ọsẹ to kọja yii.

Isẹlẹ yii waye lasiko tawọn agbebọn kọlu awọn ọdẹ ibilẹ naa ninu igbo Yargoje to wa nijọba ibilẹ Kankara nipinlẹ Katsina.

O si le ni oku awọn ọdẹ ibilẹ mọkanlelaadọrin ti wọn ti sin bayii nigba ti aayan ti n lọ lọwọ lati sawari oku awọn to le ni aadọrin, tawọn agbebọn ọhun pa.

Olugbe ilu naa kan sọ fun BBC pe o le ni ọjọ meji tawọn agbebọn ọhun atawọn ọdẹ ibilẹ naa fi n wọya ija.

Ikọlu yii si lo kan awọn eeyan to wa ni igbo Yargoje nibi ti awọn abule bii Bakori, Kankara ati Malumfashi wa.

Nilu Jargaba to wa lagbegbe Malumfashi, o le ni eeyan mẹwa ti wọn ti sin nitori ikọlu naa.

Ki lo sokunfa aawọ naa?

Iroyin to tẹ BBC lọwọ sisọ loju rẹ pe awọn agbebọn yii lo lugọ de awọn darandaran, ti wọn si ji awọn maalu wọn lọ.

Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa to ba BBC sọrọ ni “Ibọn olowo iyebiye lawọn agbebọn naa gbe lọwọ amọ ibọn ilewọ lasan lo wa lọwọ awọn ọdẹ ibilẹ naa.

Idi si niyi to fi rọrun fawọn agbebọn naa lati pa awọn ọdẹ ibilẹ yii ni ipakupa, ti wọn si bori wọn.”

Awọn eeyan agbegbe naa ni lọgan lawọn figbe ta lati beere fun iranlọwọ sugbọn ẹnikẹni ko wa seranwọ fun awọn.

Igbo Yargoje yii si lo ti jẹ ibuba nla fun ọpọ awọn adigunjale atawọn agbebọn eyi to n dunkooko mọ igbe aye awọn eeyan to wa lẹkun guusu ipinlẹ Katsina.

Lara awọn ilu to wa lẹun guusu Katsina ti ọrọ naa si kan ni ijọba ibilẹ Bakori, Malumfashi, Kafur, Kankara, Faskari ati Funtua