Àfira, ẹ dá gbogbo dúkìá ìjọba tó bá wà ní ìkáwọ́ yín padà, Adeleke pàrokò ogbè fohun fólóhun ránṣẹ́ síjọba àna l’Osun

Oyetọla ati gomina Adeleke

Oríṣun àwòrán, other

Iran awodamiẹnu to n waye lori ọrọ oṣelu ipinlẹ Ọṣun tun tẹsiwaju lọjọru pẹlu bi gomina ipinlẹ naa, Sẹnetọ Ademọla Adeleke tun ṣe gbe aṣẹ kalẹ pe ki gbogbo awọn oloṣelu ati oṣiṣẹ to ba iṣejọba ana ni ipinlẹ naa labẹ Adegboyega Oyetọla lati tete da dukia ijọba to wa ni ikawọ wọn pada lẹyẹ o ṣọka.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Ọṣun, Ọlawale Saheed fi sita lọjọru, ọjọ meji pere ni wọn fun awọn ti irufẹ dukia bẹẹ wa ni ikawọ wọn lati tete da a pada si akata ijọba ipinlẹ Ọṣun.

“Aṣẹ yii waye nitori obitibiti dukia ijọba ti awọn to ba ijọba ana ṣiṣẹ ko salọ. Ọpọlọpọ ọkọ ijọba lo ti di awati ti akọsilẹ iwe ijọba si n fihan pe ida meji ninu mẹta awọn to ba ijọa ana ṣiṣẹ ni wọn ko ọpọlọpọ ọkọ ijọba to wa ni ọfiisi wọn salọ.”

Atẹjade naa  ni ọpọlọpọ awọn ileeṣẹ ijọba ati lajọlajọ ni ko ri ọkọ, ẹrọ ayarabiaṣa kọmputa atawọn ohun elo ile, lo mọ nitori pe awọn to dari awọn ileeṣẹ ijọba ati ajọ bẹẹ ti ko ọkọ wọn lọ.

Ijọba ipinlẹ Ọṣun ni ọpọ dukia ile ijọba ti wọn gbe ni wọn tu salọ.

Yee pe afin ni adubiaran, sọ pato ọrọ lori ọrọ kiko dukia ijọba – APC

Adegboyega Oyetọla, gomina ana nipinlẹ Ọṣun, Ọọni ile ife, Ọba Adeyẹye Ogunwusi ati gomina ipinlẹ Ọṣun Ademọla Adeleke

Oríṣun àwòrán, other

Nibayii na ẹgbẹ oṣelu APC naa ko dakẹ lori aṣẹ yii ti wọn si ti ke si gomina Adeleke ati iṣejọba rẹ lati farabalẹ sọ ohun gan to ba n ṣe e nitori wohinwọhun to n ṣe ko dara fun iṣejọba.

Atẹjade kan ti Họnọrebu Sunday Akere to jẹ adari akanṣe iṣẹ lẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ ṣun rọ iṣejọba PDP nipinlẹ naa lati sọ pato ibi to n lọ gan pẹlu ẹsun kiko dukia ilu salọ to n fi kan iṣejọba ana nipinlẹ naa.

Ẹgbẹ oṣelu APC ni eyi gan ni yoo mu ki oun lee fun ijọba ni esi gbogbo to ba yẹ.

“O gbe igbimọ kan kalẹ lori ọrọ dukia yii kan naa lana ode yii. Ṣe ẹtun ti gbe igbimọ miran kalẹ lori dukia yii kan naa lọfisi gomina ni abi bawo? Ki wọn sọ ohun ti wọn fẹ gan ki a le mọ esi ti awa naa yoo fun wọn.”