Adájọ́ àgbà Adepele Ojo hùwà ta ló fẹ́ mú mi, ó gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀tọ́ wa fọ́dún mẹ́ta – Àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ gíga Osun

Osun judiciary workers

Oríṣun àwòrán, bbc

Titipa ni àwọn òṣìṣẹ́ ile ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Osun tí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ọ́fíìsì wọn lonii, Ogunjọ, oṣù Kọkànlá, ọdún 2023.

Eyi ko si sẹyin ifẹhonuhan ti awọn osisẹ ẹka eto idajọ naa ṣe lori ẹtọ wọn ti wọn sọ pe Adajọ Agba Adepele Ojo gbẹsẹ le.

Alaga fun ẹgbẹ àwọn òṣìṣẹ́ ile ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Osun, Olugbenga Olakunle Eludire, lo fi idi ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ lakoko to n ba BBC Yoruba sọrọ níbi ifẹhonuhan náà.

Eludire si ṣàlàyé ìdí tí àwọn òṣìṣẹ́ naa ṣe ti ẹnu ọ̀nà ọ́fíìsì wọ́n pa bamu-bamu.

Awọn osisẹ

Awọn ẹsun tawọn osisẹ ka si adajọ agba naa lẹsẹ ree:

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Eludire wa ka awọn ẹsun ti adajọ agba naa sẹ si ni ẹsẹẹsẹ.

“Ó ti pẹ tí Adajọ Agba Adepele Ojo ti gbẹsẹle àwọn ẹtọ wa, paapaa àwọn òṣìṣẹ́ wa ti wọ́n tí dá dúró lọ́nà tí ko tọ láti bí ọdún mẹta sẹyin, tí ko si ìgbésẹ̀ kankan tí Adajo àgbà Adepele Ojo gbe lori rẹ.”

“Gbogbo owo ajẹmọnu wa ni ko tẹ wa lọwọ látàrí bí Adajọ Agba Adepele Ojo ṣe gbẹsẹle gbogbo rẹ.

“Iwa tani ó fẹ́ mu mi ni Adajọ Agba Adepele Ojo hu sì awa òṣìṣẹ́ lábẹ́ rẹ, ṣùgbọ́n awa ko gba mọ lo jẹ ka gbe igbesẹ tí a gbe lonii yii. “

Awọn osisẹ

Tí ẹ ko ba gbàgbé pe lọsẹ to kọjá ní Gómìnà Ademola Adeleke fi ọwọ osi juwe ile fún Adajọ Agba naa fún àwọn ẹ̀sùn kan.

Àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Adajọ Agba ọhun ni pe ń se owo àwọn òṣìṣẹ́ kumọkumọ, ko tún bọ̀wọ̀ fún òfin, bẹẹ lo tun n wu ko kan mi si àwọn òṣìṣẹ́ to wa lábẹ́ rẹ.

Eyi lo fa a lọsẹ to kọjá ti Gomina Ademola Adeleke se gbe ọ̀rọ̀ rẹ lọ síwájú àwọn aṣofin ìpínlẹ̀ Osun, tí wọn sì ni ko lọ rọọkun nile fún igba díẹ̀ tí iwadi yoo fi parí lori awọn ẹ̀sùn ọhun.

Ṣé torí ìdájọ́ ikú fún Adedoyin ni ìjọba ṣe fẹ́ yọ Adájọ́ àgbà l‘Osun?

Aworan Gomina Adeleke ati Oloye Adedoyin

Oríṣun àwòrán, OSUN STATE GOVT/RAMON ADEDOYIN

Ọrọ lori aawọ to bẹ silẹ laarin ijọba ipinlẹ Osun ati Adajọ agba nigba naa si n gbona jain-jain.

Koda, ọrọ naa ti gba ọna miran yọ lẹyin ti ẹgbẹ kan ti wọn pe ara wọn ni Concerned Osun Indigenes, fẹsun kan Gomina Ademola Adeleke pe ejo rẹ lọwọ ninu lori igbesẹ rẹ.

Ẹgbẹ naa fẹsun kan Ijọba ipinlẹ Osun pe wọn gbe igbesẹ lati yọ Adajọ agba nipinlẹ Osun, Adajọ Adepele Ojo nipo nitori idajọ to gbe kalẹ lori idajọ iku ti ile ẹjọ fun Oloye Ramon Adedoyin.

Bẹẹ ba gbagbe, Adedoyin nile ẹjọ dajọ iku fun pe o lọwọ ninu iku akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo kan, Timotyhy Adegoke.

Adajọ Ojo pasẹ pe ki wọn lọ yẹgi fun Oloye Ramon Adedoyin lori ẹsun pe o lọwọ ninu iku akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo, Timothy Adegoke to ku si ile itura rẹ niluu Ile Ife.

Ninu atẹjade ti ẹgbẹ Concerned Osun Indigenes fi lede, wọn ni ijọba ipinlẹ ipinnu lati yọ Adajọ agba naa nitori o kọ lati da Oloye Adedoyin silẹ.

“Gomina Adeleke, ẹgbọn rẹ obinrin Dupe Adeleke ati Kọmisana fun eto idajọ nipinlẹ Osun, Wole Bada lo jẹ ọrẹ si Oloye Adedoyin, ti wọn si fẹ fi tipatipa yọ Adajọ agba.

“Wọn wa lọ yan Adajọ agba miiran lati ilu Ile Ife, to jẹ mọlẹbi Adedoyin lati le fun ni ominira.”

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Iroyin ofege lo n lọ yika igboro, ẹbi Adeleke ko ni ohunkohun se pẹlu ẹbi Adedoyin – Ijọba Osun fesi

Gomina Ademola Adeleke ti fesi sita lori ẹsun kan ti awọn ẹgbẹ kan fi kan pe o yọ Adajọ agba Adepele Ojo nitori idajọ rẹ to gbe kalẹ fun Oloye Ramon Adedoyin

Gomina jẹ ko di mimọ pe ko si nnkan to jẹ mọ pe oun ati mọlẹbi oun fẹ yọ adajọ agba ipinlẹ Osun nitori idajọ iku fun Oloye Ramon Adedoyin.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ijọba ipinlẹ Osun, Olawale Rasheed fi lede, Adeleke ni awọn eeyan kan n gbe iroyin ofege yii kiri nitori oun kọ lati dabobo Adajọ agba to jẹ ọmọ ilu rẹ fun jijẹjọ lori ẹsun iwa ibajẹ.

Ijọba ipinlẹ Osun sapejuwe iroyin to n lọ kaakiri naa gẹgẹ bi iroyin ofege, to si jẹ ko di mimọ pe oun ko fi igba kankan ni ibaṣepọ pẹlu Adedoyin ati idile rẹ.

“Lati ibẹrẹ ẹjọ ti de opin ẹjọ, mọlẹbi Adeleke ko da si ọrọ ileẹjọ.

Bakan naa Adedoyin ko ni ibaṣepọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu PDP tabi pẹlu Gomina.

“Adedoyin jẹ agba ọjẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, to si jẹ ọrẹ timọtimọ pẹlu Gomina tẹlẹ nipinlẹ Osun.

“Awọn agbẹjọro to n ba APC sisẹ lo jẹ agbẹjọro rẹ Adedoyin ni ile ẹjọ, eyi ti fidi rẹ mulẹ pe Ijọba ipinlẹ Osun labẹ PDP ko ni ibaṣepọ pẹlu ẹjọ Adedoyin.”

Ẹsun iwa ibajẹ wa niwaju Adajọ agba Ojo – Ijọba ipinlẹ Osun

Ninu atẹjade naa, ijọba ipinlẹ Osun jẹ ko di mimọ pe ẹsẹ Gomina Adeleke ninu ọrọ yii ni pe o kọ lati da bobo ẹsun iwabajẹ to wa niwaju Adajọ agba.

Ijọba Osun ni oun to fa rogbodiyan yii ko sẹyin ọpọlọpọ ẹsun iwabajẹ ti wọn fi kan Adajọ Ojo, ti ijọba si ni anfani lati ṣe fun ọjọ pipẹ nitori bi wọn n ṣe fi ọrọ naa kọ idajọ Adedoyin lọrun, ko to di pe Ile igbimọ aṣofin gbe igbesẹ.

“Gomina tabi idilẹ rẹ ko ni nnkan pọ pẹlu adajọ agba. Gomina ko ni da bobo ọmọ ilu rẹ kankan paapa adajọ agba to ba lọwọ nini iwa ibajẹ

“Adejọ agba ti lulẹ pẹlu bi wọn ṣe fẹ fi idajọ Adeleke kọ ijọba Osun lọrun.

“Gomina ko ni lo gbara rẹ lati dabobo ẹnikẹni koda to ba jẹ mọlẹbi rẹ.”

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí