Aboki sọ fún mi pé lóòtọ́ọ́ ni Aunty Ramota lọ fọn ìdí, tó sì wà lẹ́sẹ̀ kan aye, ẹsẹ̀ kan ọ̀run, èmi kò mọ nkànkan nípa rẹ̀ – Ìjọba Lande ṣàlàyé

Aworan ijoba Lande ati Aunty Ramota

Oríṣun àwòrán, Instagram

Gbajugbaja adẹrinposonu, Ganiyu Kehinde Morufu, ẹni ti ọpọ mọ si ijoba Lande ni o ko mọ ohunkohun nipa ohun to ṣẹlẹ si gbajugbaja oṣere tiata, Ramota Adetu, ẹni ti ọpọ mọ si Aunty Ramota ati pe ko le sọ ibi pato Ramota wa lọwọ yii

Ijoba Lande ni awọn eeyan to wa pẹlu gbajugbaja oṣere tiata Aunty Ramota ni oun da lẹbi lori iroyin to lu sita pe Aunty Ramota lọ fọn idi.

Lanaa, ọjọ kẹwaa oṣu kẹfa ọdun 2024 ni iroyin lu sita lori ayelujara pe Aunty Ramota wa ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọọrun lẹyin to ṣe iṣẹ abẹ BBL lati fọn idi.

Iroyin naa ni ile iwosan kan ni Ikorodu ni Aunty Ramota ti ṣe iṣẹ abẹ naa.

“Aboki ni kii ṣe ere sinima ni Ramota n ṣe sugbọn lootitọ ni pe Aunty Ramota lọ fọn idi”

Ijọba Lande ninu fọnran kan to gbe sori opo ayelujara rẹ fẹsun kan awọn to wa layika Aunty Ramota fun bi wọn ṣe kuna lati tan imọlẹ si ohun to ṣẹlẹ pato si Aunty Ramota.

Bẹẹ ba gbagbe, Ijoba Lande sọ fun BBC Yoruba lana pe iroyin ofege ni iroyin nipa pe Aunty Ramota lọ ile iwosan lati lọ fọn idi.

“Ẹyin ọmọ Naijiria, Aunty Ramota ko si ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọọrun; lakọkọ mo ro pe ere lasan sugbọn nigba ti mo ri fọnran pe wọn gbe Ramota wọ wọọdu ni kigba sita

“Oju gba mi ti fun Dare ati Ebute Council lori ohun to ṣẹlẹ si Ramota; paapa iwọ Aboki, o sọ pe o ko mọ ohunkohun nipa ohun to ṣẹlẹ.”

Ijọba Lande ni ọpọ igba ni oun kan si Aboki pe ko jẹwọ fun oun pe ṣe ere sinima ni Ramota n ṣe sugbọn o sọ fun oun pe otitọ ni pe Aunty Ramota lọ fọn idi.

“Mo pe Dare, Ebute Council ati Aunty Lara sugbọn wọn ko gbe ipe mi. Ni gba to ya ni mọ gba ipe pe Aunty Lara rin irinajo.

“Mo pe Aboki, mo bẹ pe ko jẹwọ fun mi to ba jẹ pe ere sinima ni fọnran Ramota to ja kiri lori ayelujara tabi otitọ sugbọn o sọ fun mi pe otitọ ni pe Ramota fọn idi.”

“N ko mọ ibi ti Aunty Ramota wa lọwọ sugbọn mo ki gbogbo lọ fọkanbalẹ nitori ere lasan ni.

Skip Instagram post

Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Content is not available

View content on InstagramBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

Aunty Ramota

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ta ni Aunty Ramota?

Ramota Adetu, ti ọpọlọpọ maa n pe ni Aunty Ramota jẹ ọmọ bibi ilu Ikorodu nipinlẹ Eko, ọdun 1981, eyiun ọdun mẹtalelogoji sẹyin ni wọn bi sile aye.

Amọ Aunty Ramota ni aisan kan lara eyi ti ko jẹ ko dagba soke, to si ri kekere bi ọmọde, ti ko si dabi agbalagba rara.

Ọdun mẹta sẹyin ni mama Ramota ku, ti ko si si ẹni to mọ nipa baba rẹ.

Osere tiata ni Ramota, to si tun maa n dẹrin pa osonu.

Bo se da bi ọmọde lo mu ki ọpọ eeyan nifẹ lati wo, to si maa n se ọmọ ile ẹkọ pẹlu gbajumọ adẹrinposonu miran, Ijaba Lande.