Ààrẹ Tinubu darapọ̀ mọ́ àwọn Mùsùlùmí láti kírun yídì Eid-el-Kabir nílùú Eko

Aarẹ Tinubu ni Yidi Dodan Barracks

Oríṣun àwòrán, Dare Idowu/Channels TV

Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu darapọ mọ awọn musulumi lati kirun yidi ọdun ileya ni Dodan barracks to wa ni Iloyi nilu Eko lọjọ Aiku.

Odun Eid Kabir jẹ ọdun awọn musulumi jakejado agbaye eyi ti wọn maa n ṣe ni ọjọ kẹwaa oṣu Dhual-Hijjah.

Aarẹ Tinubu gunlẹ si yidi naa ni nnkan bii agogo mẹsan an ku iṣẹju marun un lọjọ Aiku.

Awọn oṣiṣẹ ijọba Naijiria to dara pọ

Oríṣun àwòrán, Channels TV

Olori awọn to n ba aarẹ ṣiṣẹ, Fẹmi Gbajabiamila, adari eto abo ni Naijiria, Nuhu Ribadu; igbakeji gomina ipinlẹ Eko, Ọbafẹmi Hamzat; Gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Eko, Babatunde Fashọla, agba oniṣowo ni, Aliko Dangote at’awọn eekan ilu miran.

Saaju ni aarẹ ti kọkọ darapọ mọ awọn ọmọ Naijiria lati woye lori pataki ajọdun Eid-el-Kabir, eyi to ni o mu itumọ pataki dani fun orilẹede Naijiria lọwọ yii.

Awọn oṣiṣẹ ijọba Naijiria to dara pọ

Oríṣun àwòrán, Channels TV

Ninu oro to ba awọn ọmọ Naijiria sọ, aarẹ rọ awọn ẹlẹsin musulumi jakejado Naijiria lati tẹlẹ ilana ifaraẹnijin, igbagbọ ati igbọran si aṣẹ Ọlọrun gẹgẹ bi ajọdun naa ṣe laa kalẹ.

“Aarẹ mọ riri ifara ẹnijin awọn ọmọ Naijiria lati ọdun kan sẹyin bi iṣejọba rẹ ṣe n gbe igbesẹ lati fi ẹsẹ Naijiria le ori ọna idagbasoke ati ilọsiwaju.”

Aarẹ Tinubu ni Yidi Dodan Barracks

Oríṣun àwòrán, Dare Idowu/Channels TV

Aarẹ Tinubu rọ awọn ọmọ Naijiria lati tubọ maa gbadura fun orilẹede naa fun alaafia lati jọba bi oun tikara ṣe n ṣiṣẹ lati mu iṣọkan, alaafia ati ilọsiwaju gogo si.

O wa tun tẹnumọ pe isejọba oun n mu igbayegbadun alaafia ati eto ọrọ aje lọkunkundun, ko si ni sinmi ninu afojusun rẹ.