
Oríṣun àwòrán, AFP/Reuters
Aarẹ orilẹede Liberia, George Weah ni oun ti pe alatako rẹ ninu eto idibo aarẹ, Joseph Boakai lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ lati ki ku orire bo ṣe jawe olubori ninu eto idibo.
Ninu ọrọ rẹ si awọn araalu O ni “Awọn araalu Liberia ti sọrọ, a dẹ ti gbọ ohun ti wọn sọ”.
Boakai lo n lewaju bayii pẹlu ibo toto ẹgbẹrunlọna mejidinlọgbọn, to si jẹ pe diẹ lo ku ki wọn ka gbogbo ibo naa tan.
Agbabọọlu tẹlẹri, Weah lo ti wa nipo agbara lati ọdun 2018, ti yoo si gbe agbara silẹ ninu oṣu kini ọdun to n bọ.
Boakia naa ni alatako rẹ ọdun 2018, to si fidi rẹ janlẹ sugbọn nnkan ti yi pada bayii lọdun 2023.
Bi iṣejọba Weah ṣe kuna lati gbe ogun ti iwa ibajẹ, ọwọngogo nnkan ni ilu ati bi eto ọrọ aje ṣe mẹyẹ ti tabuku si orukọ rẹ.
Nigba ti o n sọrọ, Weah ni oun bọwọ fun ilana eto idibo ati ijọba awarawa, to si ni oun ti kan si Aarẹ tuntun lati ki ku orire bi o ṣe jawe olubori.
O wa rọ awọn eeyan Liberia lati sisẹ pọ pẹlu Aarẹ tuntun lati mu ayipada ba orilẹede Liberia nitori iṣokan ṣe pataki.
Saaju ajọ eleto idibo Liberia kede pe Boakai, ẹni ọdun mejidinlọgọrin lo n lewaju idibo aarẹ pẹlu ida ibo 50.89% ti Aarẹ Weah si ni ida ibo 49.11%.
Ariwo ayọ sọ bi wọn ṣe kede esi ibo tuntun lọjọ Ẹti ni Monrovia.
Awọn ololufẹ Boakia ṣe ajayọ ni ofisi ẹgbẹ oṣelu rẹ to wa niluu Monrovia kete ti wọn gbọ pe awọn ti bori ibo aarẹ.

Oríṣun àwòrán, Others