Ààrẹ Bola Tinubu yóò bá àwọn ọmọ Naijiria sọ̀rọ̀ láàrọ́ òní

Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Aarẹ Bola Tinubu yoo ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ laarọ oni ọjọ kejila, oṣu Kẹfa, ọdun 2024, to jẹ ayajọ iṣe jọba awarawa, ‘June 12’.

Ni dede aago meje aarọ ni Aarẹ yoo ba awọn araalu sọrọ lori ẹrọ amohunmaworan.

Ọọfisi Aarẹ ti wa ke si gbogbo ileeṣẹ amohunmaworan ni Naijiria atawọn ileeṣẹ redio ki wọn darapọ mọ ileeṣẹ igbojunsafẹfẹ ijọba apapọ, NTA ati Radio Nigeria, ki ọrọ naa le de tile toko.

Ikede yii lo jade ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Aarẹ, Ajuri Ngelale, fi lede lọjọ Iṣẹgun.

Gbogbo ọjọ kejila, oṣu Kẹfa, ọdọdun ni ayajọ iṣejọba awarawa ni Naijiria.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ayajọ ọjọ yii ni wọn kọkọ fi n ṣe iranti agba oloṣelu ni to di oloogbe, MKO Abiola.

Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un ni ayajọ iṣejọba awarawa tẹlẹ ni Naijiria ki wọn to yipada si ọjọ kejila, oṣu Kẹfa.

Ẹwẹ, bo tilẹ jẹ pe ọjọ iranti ati ajayọ ijọba awara ni ọjọ yii jẹ fun ijọba Naijiria, ọpọ araalu lo maa n fi ayajọ ọjọ naa sọko ọrọ si ijọba latari bi eto ọrọ aje Naijiria ṣe ri, koda awọn mii maa n fi ọjọ naa ṣe ifẹhonuhan.

Wayi o, ọpọ araalu lo n reti ohun ti Aarẹ yoo sọ, paapaa lori eto ọrọ aje to denukọlẹ, ọwọngogo epo bẹntiro, ọwọngogo ounjẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.