A ò fẹ́ Ọba tipátipá tí Gómìnà gbé lé wa lórí ní Ikirun, ìwọ̀sì ló fi wọ̀ wá! – Eesa Ikirun

Ọkan lara awọn oloye ilu Ikirun to jẹ Eesa, Oloye Lawal Adetoyese ba BBC Yoruba sọrọ lori gbogbo laasigbo ati idamu to n ṣẹlẹ ni ilu naa.

Bi ẹ ko ba gbagbe, igba ti iṣoro yii bẹrẹ ni akoko ti wọn yan Ọba tuntun amọ ti awọn araalu yari wipe awọn ko fẹ Ọba naa ti wọn si bẹrẹ lọjọ naa pẹlu ṣiṣi ifẹhonuhan lọ si aanfin.

Wọn o daa mọ ọ nibẹ o tun ni ọjọ ti awọn ọdọ tu sita lọ di awọn kọngila to n ṣiṣẹ ni aafin duro, awọn Ọlọpaa da sii amọ nigbẹyin gbẹyin wọn sọ ina si odidi aafin

Ọba to si tun fa iku awọn kan lara wọn.

O tun ṣalaye bi wọn ṣe wa fi ofin gbe afọbajẹ mẹfa kuro ni aafin lorukọ gomina to wa lori alefa nigba naa lọhun, Gboyega Oyetola.

Eesa Ikirun

Ohun to n ṣẹlẹ ni Ikirun ko ye awọn ara ita

Awọn ara ita ti kii ṣe ọmọ ilu Ikirun ko tilẹ mọ ki ni o wa nidii nnkan to n ṣẹlẹ to fi buru bẹẹ.

Eyi ni Eesa ti ilu Ikirun ṣe lalaye lẹkunrẹrẹ fun BBC Yoruba.

O ṣalaye pe idile mẹta lo n jẹ Ọba nilu Ikirun to si ṣalaye idile to ṣe kọja to si kan idile mii.

“O dabi ẹni pe idile to kan ko ri eeyan kankan fa silẹ to si wa di ẹrẹẹ si ilu lọrun.

Eyi lo faa ti ile ẹjọ ṣe ni ki wọn bọ si idile kẹta ọhun lati yan Ọba.”

Ọjọ Kọkandinlogun Oṣu Kẹwa Ọdun 2021 ni Eesa ni gbogbo rogbodiyan yii bẹrẹ gangan.