A kò ní pe Ọlọ́run ní ẹjọ́ lórí ìkú ọmọ wa, Dare Adeboye – Ẹbí Adeboye

Pasitọ Adeboye ati ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, PST DEE

Ẹbi oloogbe Pasitọ Dare Adeboye ti ni awọn ko ni pe Ọlọrun ni ẹjọ lori iku ọmọ wọn nitori o gbe igbe aye to wuyi.

Ọjọ Iṣẹgun, Ọjọ Kẹrin, Osu Karun un, ọdun 2021 ni Dare Adeboye jade laye ni ẹni ọdun mejilelọgoji nigba ti o sun ti ko ji.

Lati igba to the di oloogbe naa ni awọn eniyan ti n fi ọrọ ibanukẹdun ranṣẹ si baba oloogbe naa to jẹ adari ijọ Redeem lagbaye, Pasitọ Enoch Adeboye.

Ninu iwaasu rẹ lasiko isin oloṣooṣu Holy Ghost Service, Baba Adeboye ni Ọlọrun jọba lori ohun gbogbo ti ko si si ẹni to le e pe ni ẹjọ lori iṣẹlẹ kankan.

”Ohun gbogbo ti Olorun ba fun wa ni ile aye, iba ṣe ọrọ, iyawo, ọkọ, ọmọ, to si tun gba a pada ni ọwọ wa, o yẹ ki a fi ogo fun Ọlọrun ni nitori Oun naa lo fun wa ni oreọfẹ lati gbadun gbogbo ohun to fun wa fun igba diẹ, to fi mọ awọn ọmọ wa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

”Nitori naa, ko tọ si wa lati ba Ọlọrun ro ẹjọ tabi ki a daa lẹbi , nitori oun lo fun wa ni gbogbo ohun ti a ni.”

”Ninu Ohun gbogbo, ẹjẹ ki a kọ lati ma a sọ wi pe mo dupẹ Baba ati wi pe yoo dara. Ki Oluwa wa pẹlu gbogbo wa.”

Aburo oloogbe naa, Leke Adeboye sọ fun ileeṣẹ iroyin Punch wi pe awọn ko ni ẹjọ kankan lati ba Ọlọrun ro nitori pe ko si nkankan to le e ya wa kuro ninu ifẹ Ọlọrun wa gẹgẹ bi iwe mimọ ti wi.

Bakan naa ni O fikun wi pe iṣẹ ti ẹgbọn ṣe nigba to wa ni aye yoo ma fọhun si titi ayeraye, nitori pe o sin Ọlọrun tọkantọkan, to si sa ipa rẹ fun awọn ọdọ to wa ni ijọ Redeem.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

”Nigba ti a n dagba, a ṣe ohun gbogbo papọ ni to fi mọ lilọ si ileewe kan naa ati fifẹ iyawo ni ọjọ kan naa pẹlu ọdun diẹ si ara wọn.”

”Oun lo kọ mi lati sa gbogbo ipa mi ninu gbọgbọ ohun ti mọ ba n ṣe, lai fi imẹlẹ ṣe iṣẹ Oluwa.”

Nibayii, awọn ẹbi ti fi lede wi pe Ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní olóògbé yóò wọ káà ilẹ̀ ṣùn ní Redemption Camp.