A fura pé IPOB àti ESN ló wà nídìí ikú alága ìjọba ìbílẹ̀ tí àwọn agbébọn bẹ́ lórí – Ọlọ́pàá Imo

CHRIS OHIZU

Oríṣun àwòrán, CHRIS OHIZU/FACEBOOK

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo ni iwadii ti bẹrẹ lori iku Chris Ohizu, to jẹ alaga ijọba ibilẹ ariwa Ideato, nipinlẹ Imo, eyi ti awọn bẹ lori lẹyin ti wọn gba owo itusilẹ rẹ tan.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Henry Okoye fi lede, o ni awọn funra pe awọn ọmọ ẹgbẹ ajijagbara IPOB ati ESN lo wa nidi iku ọkunrin ọhun.

Okoye ni “A fẹ fi akoko yii sọ fun awọn eeyan ipinlẹ Imo pe a ti bẹrẹ iwadii ọrọ naa, a si ti n wa awọn afunrasi ọhun ṣaaju ki fidio naa to jade.”

O sọ siwaju si pe awọn ọlọpaa ko ni sinmi titi ti ọwọ yoo fi tẹ awọn to ṣiṣẹ laabi ọhun.

Bi wọn ṣe bẹ ori alaga ijọba ibilẹ ariwa Ideato

Ṣaaju ni fidio kan ti kọkọ jade lori ayelujara, eyii to safihan bi awọn agbebọn kan ṣe da oloogbe naa kunlẹ, ti wọn si n dukoko mọ pe awọn yoo gbẹmi rẹ.

Yatọ si ọkunrin ọhun, awọn agbebọn naa tun ṣeleri pe awọn yoo ṣekupa gomina ipinlẹ Imo, Hope Uzodima.

Wọn ni awọn kii ṣe ọmọ ẹgbẹ IPOB ninu fidio naa, amọ awọn ko fẹ ki eto idibo kankan waye nipinlẹ Imo.

Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, bi wọn ṣe pa ọkunrin naa ni awọn yoo ṣe gbẹmi gomina Uzodima.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ko pẹ si asiko ti wọn dukoko naa tan ti wọn ge ori ọkunrin ọhun.

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si n fi aidunu wọn han si iku alaga ijọba ibilẹ naa.

Oru Ọjọbọ to kọja ni awọn agbebọn naa lọ ji oloogbe ọhun gbe nile rẹ ki wọn to sọ ina si ile ọhun.

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?

Àwọn agbébọn bẹ́ orí alága ìbílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba owó itusile

Aworan CHRIS OHIZU

Oríṣun àwòrán, CHRIS OHIZU/FACEBOOK

Alaga ibilẹ ariwa Ideato nipinlẹ Imo, Chris Ohizu ni awọn afurasi agbebọn ti bẹ ori rẹ lẹyin ti wọn gba owo itusilẹ lọwọ awọn mọlẹbi.

Ohizu ni wọn bẹ lori lọjọ Aiku lẹyin ti awọn agbebọn gba milọnu mẹfa naira, owo itusilẹ.

Fọnran isẹlẹ naa lo gba ori ayelujara lọjọ Akiu, ọjọ kejilelogun, oṣu kinni ọdun 2023, ti awọn agbebọn naa si n pariwo pe ko ni si eto idibo lọdun yii lorilẹede Naijiria.

Ọkan lara awọn osisẹ ijọba ibilẹ naa to ba ileeṣẹ BBC News sọrọ ni awọn agbebọn naa gbe fọnran bi wọn bẹ ori alaga naa sori ayelujara rẹ, lori ‘Whatsapp Status’.

O ni “Wọn ti bẹ ori alaga ibilẹ. A ri fidio bi wọn ṣe bẹ lori lọjọ Aiku.”

“Awọn to ṣekupa lo gbe fọnran naa sori opo ayelujara Whatsapps rẹ. Ibi ti a ti mọ pe wọn ti bẹ lori niyẹn.”

“Nnkan buruku ni fọran naa, wọn so mọ igi, ti wọm si ja si ihoho. Ọna buruku lati padanu ẹmi eeyan niyẹn, wọn bẹ lori lẹyin ti wọn gba milọnu mẹfa owo itusilẹ.”

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Imo, Henry Okoye fi idi isẹlẹ naa mulẹ, to si ni iwadii ti bẹrẹ lori isẹlẹ naa.

Lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja ni awọn afurasi ajinigbe agbebọn wọle alaga ati awọn meji miiran lẹyin ti wọn dana sun ile gbe rẹ ni ilu Imoko ni agbegbe Arondizuogu ni ijọba ibilẹ ariwa Ideato.