Àṣìṣe dókità ló pa Peju, ìbànújẹ́ dorí àgbà kodò- Funke Akindele

#Justice for Peju:

Oríṣun àwòrán, @Funke Akindele

Peju fi omodebinrin meji, iya ati ọkọ silẹ lọ lataari aṣise awọn dokita- Funke Akindele.

Loju opo Instagram ni gbajugbaja oṣere ni, Funkẹ Akindele ti ke gbajare pe iku awọn eeyan lati ọwọ aṣiṣe dokita to gẹ.

Arabinrin Peju Ugboma lo fi ẹsẹ ara rẹ rin wọ inu ile iwosan Premiere Hospital nibi to ti lọ fun iṣẹ abẹ oyun iju to n yọ ọ lẹnu.

Funkẹ Akindele ṣalaye pe, ṣaaju ni ile iwosan yii ti ṣe ayẹwo gbogbo ẹya ara Peju Ugboma ki wọn to sọ pe ki o wa ṣe iṣẹ abẹ naa lasiko yii.

Akindele ni oku Peju ni wọn gbe sita lẹyin ọjọ meji nibẹ ti iwadii lẹyin iku rẹ si fihan pe aṣiṣẹ dokita lo ṣe iku pa a.

Funke Akindele ṣalaye siwaju pe leyin ti wọn pari iṣẹ abẹ naa ni Peju Ugboma ji saye to si sọ pe inu n dun oun ni eyi ti awọn ẹbi rẹ si kan si dokita wọn kan nilẹ okere.

#Justice for Peju:

Oríṣun àwòrán, @Funke Akindele

Dokita naa ni o ṣeeṣe ko jẹ pe Peju n da ẹjẹ lati inu ni pẹlu awọn iwoye ti ẹbi sọ fun oun yii.

#Justice for Peju:

Oríṣun àwòrán, @Funke Akindele

Lẹyin na ni ẹbi Peju si sọ fun awọn dokita ile iwosan Premiere Hospital oun ti dokita sọ yii ṣugbọn won ko ka kun.

#Justice for Peju:

Oríṣun àwòrán, @Funke Akindele

Leyin naa ni wọn ṣẹṣẹ wa gbe Peju lọ sile iwosan mii nibi ti wọn ti ni o ku ko to de ibẹ.

#Justice for Peju:

Oríṣun àwòrán, @Funke Akindele

Ariwo ti Funke Akundele ati awọn ọmọ Naijiria miran n pa ni pe #Justicefor Peju.

#Justice for Peju:

Oríṣun àwòrán, @Funke Akindele

Eyi ti wọn fi ni kile iwosan Premiere Hospital wa wẹ yan kainkain lori iku to pa Peju ati awọn aṣiṣe ti wọn ṣe.

#Justice for Peju:

Oríṣun àwòrán, @funke Akindele

Ebi ni bi Premiere Hospital ṣe beere fun ẹjẹ ni wọn ti fi igo mẹsan an silẹ nitori Peju ni eyi to fihan pe gbogbo igbese awọn dokita ibẹ ja si aṣiṣe to si gab ẹmi arabinrin ọlọmọ meji naa.

#Justice for Peju:

Oríṣun àwòrán, @funke Akindele

Bakan naa ni awọn ọmọ Naijiria n pariwo lori ayelujara pe ki awọn eniyan maa pariwo awọn dokita to n ṣe aṣiṣe lori alaisan sita ki a le dẹkun iku awọn alaisan nipa se aṣiṣe awọn dokita Naijiria.