‘Ohun tí àwa Ọba àlayé ń retí lọ́dọ̀ Gómìnà wá Ademola Adeleke nìyí’

Awọn Ọba

Bí gómìnà Ademola Adeleke ṣe gba ọ̀pá àṣẹ ní ìpínlẹ̀ Osun láti darí ìpínlẹ̀ náà fún ọdún mẹ́rin ní àwọn ènìyàn ti ń ké sí ìjọba tuntun náà láti mú gbogbo ìlérí tí wọ́n ṣe lásìkò ìpolongo ìbò ṣẹ.

Àwọn ènìyàn ń rán ìjọba létí pé ìdí tí àwọn ènìyàn fi dìbò fun ìjọba tuntun náà kò gbọdọ̀ lọ lásán nítorí ìgbẹkẹ̀lé tí wọ́n ní nínú ìjọba ga púpọ̀.

Báwọn ènìyàn ṣe ń gba ìjọba lámọ̀ràn yìí náà ni wọ́n ń gbàdúrà fún wọn wí pé àṣeyè tí alákàn ń ṣepo ni ìjọba yóò ṣe.

Àwọn orí adé ọrùn ìlẹ̀kẹ̀ tó báwọn péjú pésè níbi ètò ayẹyẹ ìbúrawọlé fún gómìnà Ademola Adeleke náà fi ìrètí wọn nínú ìjọba tuntun náà hàn.

À ń rétí fífún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ní ààyè láti ṣèjọba lọ́wọ́ ara wọn látọwọ́ gómìnà tuntun – Oluwo

Lára àwọn orí adé tó bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ ni Oluwo ti ìlú Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi Adewale, tó sì sọ wí pé òun gbàgbọ́ wí pé ìpínlẹ̀ Osun yóò tún rí ìdàgbàsókè tí gómìnà tuntun bá mú àwọn ìlérí tó ṣe fún ará ìlú ṣẹ.

Ọba Akanbi ní “Tí gómìnà bá ṣe gbogbo àwọn nǹkan tí ó kà nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ìdẹ̀kùn yóò bá àwọn ará ìpínlẹ̀ Osun nílé lóko.”

Bákan náà ló tún gbàdúrà fún gómìnà tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dórí ipò náà wí pé Ọlọ́run yóò fun ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye tí yóò ṣe ìjọba ìpínlẹ̀ Osun.

“Kí ìgbà Ademola Adeleke gẹ́gẹ́ bí gómìnà mú ìtura bá ará ìlú nítorí òun tí òun máa ń wá gẹ́gẹ́ bí gómìnà ni bí ara yóò ṣe tu ará ìlú.”

Ó rọ́ gómìnà láti mú ìlérí rẹ̀ ṣe nítorí àwọn ará ìlú ǹí ìrètí tó ga nínú rẹ̀ ni wọ́n ṣe dìbò yàn-án.

Oluwo ní lára àwọn nǹkan tí gómìnà tuintun ṣèlérí ni fífún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ láàyè láti ṣiṣẹ́ láyè ara wọn, Oluwo ní irúfẹ́ ìgbésẹ̀ báyìí yóò kí èrèjẹ ìjọba dé ẹsẹ̀ kùkú, tí tọmọdé tàgbà yóò sì rí àǹfàní ìjọba jẹ.

Timi ìlú Ede, Ataoje ìlú Osogbo náà sọ̀rọ̀ lórí àyípadà tó bá ìjọba tuntun

Timi ìlú Ede, Ọba Munirudeen Adesola Lawal gba Gómìnà Ademola Adeleke níyànjú láti mú ri pé àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jáde dìbò fún-un rí èrè ìjọba tuntun jẹ àti pé wí pé kó ṣe àrídájú rẹ̀ pé ìjọba rẹ̀ ní ipa rere nínú ìgbésí ayé wọn.

Ọba Lawal wá rọ àwọn ọ̀dọ́ náà láti ran ìjọba lọ́wọ́ lọ́nà tí ìjọba yóò fi lè pèsè àwọn nǹkan tí yóò mú ìdẹ̀kùn báwọn fún wọn.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, Ataoja of Osogbo Ọba Jimoh Olanipekun Oyetunji rọ̀ àwọn ará ìlú láti ṣe sùúrù pẹ̀lú ìjọba tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dorí oyè kí wọ́n fi ọ̀nà ti wọ́n yóò fi mú ìgbà ọ̀tún bá ìpínlẹ̀ Osun nítorí ṣíṣe àtúnṣe sí àwọn nǹkan tó bá ti bàjẹ́ kìí yá bọ̀rọ̀.

Ọba Oyetunji rọ ìjọba láti tètè dá àwọn ará ìlú lóhùn ohun gbogbo tí wọ́n ń fẹ́ nítorí ọ̀pọ̀ ará Osun ni ìgbé ayé kò rọrùn fún.

Ìpèsè iṣẹ́, ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ àti ìlera tó péye ni àwa ń fẹ́ – ará ìlú

Nígbà tí BBC Yorùbá kàn sí àwọn ará ìlú láti mọ ohun tí wọ́n ń fẹ́ lọ́wọ́ ìjọba tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbapò ní ìpínlẹ̀ Osun, òun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ń bèèrè fún ni ìdásílẹ́ ilé iṣẹ́.

Wọ́n gba ìjọba ní ìmọ̀ràn láti ní àjọṣèpọ̀ pẹ̀lú àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá láti gbé ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wọn wá sí ìpínlẹ̀ Osun kó le ọ̀nà láti pèsè iṣẹ́ fún ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ìpínlẹ̀ náà.

Bákan náà ni wọ́n tún ń bèèrè fún ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ kí àwọn ọmọ mẹ̀kùnú le kàwé dé ibi tó bá wù wọ́n láì sí ìbẹ̀rù tàbí ohun kóhun tí yóò dí wọn lọ́wọ́.

Ohun mìíràn tí àwọn ènìyàn túnń fẹ́ kí ìjọba mójútó ni bí ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Osun yóò ṣe tún rú gọ́gọ́ jù bó ṣe wà lọ.

Wọ́n ní bí àwọn òṣìṣẹ́ bá ń gba owó oṣù wọn lásìkò, tí ìpèsè iṣẹ́ náà sì wà fún àwọn ọ̀dọ́, wọ́n ní ó di dandan kí àyípadà gidi bá ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ náà.

Wọ́n tún tẹ̀síwájú pé ìlera lògùn ọrọ̀ nítorí náà kí ìjọba pèsè ètò ìlera tí yóò gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gba àwo bọ̀ kí tolórí tẹlẹ́mù jẹ́ mùkúndùn ìjọba àwaarawa.