Iléẹjọ́ ní kí akẹkọọ fáṣítì tó sọ̀rọ̀ àlùfánsí sí ìyàwó Ààrẹ Aisha Buhari máa gbà àtẹ̀gùn ní ahàmọ́.

Aworan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ọpọlọpọ awuyewuye lo ti jẹyọ lẹyin ti awọn agbofinro mu akẹkọọ fasiti kan to tabuku sì aya aarẹ Orilẹede Naijiria, Aisha Buhari lori opo Twitter.

Aminu Adamu Mohammed ti wa ni ọgba ẹwọn bayii, ti Agbẹjọro rẹ Chijioke Kingsley Agu sọ fun Ileeṣẹ BBC pe akẹkọọ naa ni wọn ti gbe lọ ileẹjọ giga Maitama niluu Abuja lọjọ isẹgun 

Akẹkọọ ọhun ni wọn fi ẹsun ọdaran tí Agbẹjọro rẹ si ti bere fun beeli rẹ, eyi ti ireti wa pe ileẹjọ yoo buwọlu laarin ọjọ meji.

Ọkùnrin naa ẹni mejilelogun ni ọwọ awọn ileeṣẹ ọlọpaa tẹ lẹyin to gbe aworan iyawo aarẹ si ori opo ayelujara Twitter, ti o si kọ si pe ninu ede Hausa pe o n sara sì pẹlu owo awọn araalu.

Akẹkọọ ọhun ni o yẹ ko kopa ninu idanwo pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ ni ọsẹ to n bọ sugbọn ko si ireti pe yoo ni anfani lati kopa ninu idanwo naa.

Ọpọlọpọ awọn eeyan lori ayelujara lo ti bu ẹnu atẹlu igbesẹ ìjọba apapọ tí wọn si n bere fun itusile akẹkọọ naa.

Nibi oṣu diẹ sẹyìn ni awọn ofin mu awọn meji, tí wọn si bo ẹgba sì idì nitori wọn wu iwa ibanilorukọ jẹ fun Gomina ipinlẹ Kano lori opo ayelujara Tiktok.

Àwọn òbí ọmọ tí wọ́n tì mọ́lé nítorí ó bú Aisha Buhari ti sọ̀rọ̀ sókè

Awọn obi ọmọ Fasiti kan ni ipinlẹ Jigawa, Aminu Adamu Mohammed ti wọn fi ẹsun kan pe o bu iyawo aarẹ Niajiria, Aisha Buhari ti sọrọ soke

Awọn obi naa ninu ọrọ wọn ti tọrọ aforiji lọwọ iyawo aarẹ, Aisha Buhari lati dariji ọmọ naa.

Iroyin ni awọn ẹṣọ alaabo gbe akẹkọọ ileẹkọ Fasiti Dutse ni ipinlẹ Jigawa.

Kini Aminu Mohammed kọ si Twitter?

Ninu ọrọ ti ọmọ naa fi si oju opo Twitter rẹ lo ti fi fọtọ Aisha si bẹ, to si kọ ọrọ ni ede Hausa pe, Aisha Buhari ti sanra si nitori o ti ko owo araalu jẹ.

Wọn ni ọjọ Kẹjọ, Osu Kẹfa, ọdun 2022 lo fi tweet ọhun si oju opo Twitter rẹ, to si fi ẹdẹ abinibi rẹ kọ

Amọ ileeṣẹ iroyin BBC ko lee fi idi ọrọ naa mulẹ lori Twitter.

Kini awọn obi rẹ sọ?

Aworan

Oríṣun àwòrán, AMNESTY INTERNATIONAL

 Awọn obi Aminu Adamu Mohammed ni ipe ni an gba lati ọwọ ẹnikan pe ọmọ rẹ wa ni Abuja lẹyin ti ẹṣọ alaabo gbe lori nkan to kọ si oju opo ikansiraẹni Twitter.

Mọlẹbi rẹ to sọrọ ni orukọ ebi, Shehu Baba Azare ni awọn ti bẹbẹ ki iyawo aarẹ dariji awọn, ki wọn si dariji.

‘’Ohun ti a mọ nipe iya wa ni iyawo aarẹ jẹ nitori naa ni a ṣe n ra wọ ẹbẹ si lati dariji wa , ki wọn fi Aminu silẹ’’

Bakan naa ni ọkan lara awọn akẹkọọ to ba BBC Pidgin sọrọ ni idanwo ileẹkọ n bẹrẹ ni ọṣẹ to n bọ, nitori naa ki wọn jọwọ fi silẹ ni kiakia, ki o ma ba daamu rẹ ati esi idanwo rẹ.

Kini awọn eniyan sọ?

Ọpọlọpọ eniyan ati ẹlẹgbẹjẹgbẹ lo ti fi ero wọn han lori iṣẹlẹ naa, to si ti gba ori ẹrọ ayelujara kan.

Loju ọpọ Twitter ati oju opo ikansiraẹni miran ni #FreeAminuAdamuMohammed ti n trend.

Awọn eniyan n pe fun ki wọn fi akẹkọọ ọhun silẹ.

Bakan naa ni Ajọ Ajafẹtọ ọmọniyan, Amnesty International naa ti pe fun itusilẹ rẹ ni kiakia.

Wọn ni o lodi si ofin ki wọn tii mọle lai ni ẹtọ si agbẹgbọro ati awọn eniyan rẹ.