₦62,000 tí ìjọba fi lọ̀ wá kò tẹ́ wa lọ́rùn, a kò fẹ́ ₦100,000, ₦250,000 ni a fẹ́ – NLC/TUC

NLC

Oríṣun àwòrán, @abdullahayofel

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ni Naijiria ti sọ pe oun ko ni gba owo to kere ju N250,000 gẹgẹ bii owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.

Igbakeji akọwe agba ẹgbẹ oṣiṣẹ, NLC, Chris Onyeka ni N62,000 ti ijọba fi lọ awọn ko ṣe itẹwọgba, bẹẹ lawọn ko ni gba N100,000 ti awọn eeyan kan ni ki awọn gba.

Ọrọ yii lo n jade lẹyin ti alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ọhun, Joe Ajaero sọ pe awọn n duro de esi Aarẹ Bola Tinubu lori ọrọ naa ati igbesẹ ti yoo gbe.

Lọjọ Aje ni ọọfisi akọwe ijọba apapọ jabọ pe igbimọ to n jiroro lori ọrọ owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ naa ti jabọ ijiroro rẹ fun ijọba.

Ṣaaju lẹyin ipade igbimọ ọhun ni ijọba ti kọkọ sọ sọ pe N62,000 ni agbara oun gbe gẹgẹ bii owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ, ti ẹgbẹ oṣiṣẹ si yari pe owo ọhun ti kere ju, ati pe N250,000 lawọn n fẹ.

Ẹwẹ, bi awọn araalu ṣe n jẹ ọrọ naa lẹnu ni ẹgbẹ awọn gomina ni Naijiria kede pe awọn ko tilẹ ni le san owo oṣiṣẹ to kere julọ to ba le ni N60,000.

Lana ọjọ Aje, agbenusọ igbimọ ijọba to n jiroro lori ọrọ naa, Segun Imohiosen, sọ pe igbimọ naa ti “pari ijiroro rẹ, o si ti fun akọwe ijọba apapọ ni ohun to ba bọ lọjọ Aje, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹfa, ọdun 2024.

“Wọn yoo fun Aarẹ ni esi naa ti awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ, aṣoju ijọba atawọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ aladani ba pada de lati apero ẹgbẹ oṣiṣẹ agbaye ti wọn lọ ṣe ni Geneva, Switzerland.”

“N62,000 ko tẹ wa lọrun”

Wayi o, nigba to n sọrọ lori nibi iforowerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Channels, igbakeji akọwe NLC, Nyeka ni “ohun ti a fẹ han kedere, a ko fẹ N62,000 tabi wo oṣu kankan ti a mọ pe o kere ju ohun ti awọn oṣiṣẹ le maa mu lọ sile ni ipari oṣu.

“A kọ lati jiroro lori owo oṣu ti yoo fi ebi pa awọn oṣiṣẹ.

“A ko tilẹ sọ pe a fẹ N100,000 gan, anbelete N62,000, ohun ti a ṣi duro le lori ni N250,000; ibi ti wa niyẹn, ohun ti a le tẹwọgba niyẹn.