Ṣíṣe oríire nínú iṣẹ́ sinimá kò ṣẹ̀yin mọ̀lẹ́bí ìyàwó mi Mide Martins – Afeez Owo

Aworan Mide Martins, Afeez Owo ati Funmi Martins

Oríṣun àwòrán, MIDE FUNMI MARTINS/FACEBOOK

Gbajugbaja oṣere ati oludari fiimu agbelewo lede Yoruba, Afeez Abiodun, ti ọpọ eniyan mọ si Afeez Owo, ti wi pe ipa ti mọlẹbi iyawo rẹ ko nile aye rẹ ko kere rara ati pe o ṣe ọpọlọpọ ran lọwọ fun un.

Afeez, to ṣalaye ibaṣepọ to wa laarin oun ati iya iyawo rẹ, Funmi Martins, nigba aye rẹ wi pe iwa iya lo fa ifẹ ti oun ni si iyawo oun.

Ninu ifọrọwerọ lori eto kan ti wọn pe ni ‘Talk to B’ pẹlu Biola Adebayo ni Afeez ti sọ gbogbo bi oun ṣe gbe pẹlu Funmi Martins ninu yara kan ni Mushin, pẹlu awọn mọlẹbi Funmi meji ti gbogbo wọn jẹ mẹrin ninu yara kan naa.

Afeez tẹsiwaju pe Mide de waa ba awọn ninu ile naa lati ilu oyinbo ti wọn si jọ n gbe pọ nibẹ.

Adari ere naa wi pe nigba aye iya iyawo oun, o maa n bẹ oun lati da sẹria fun Mide to ba ṣẹ ninu ile.

O fikun pe ifẹ ti Funmi Martins ni fun oun ati ibagbepọ oun ati Mide lo fa ifẹ laarin awọn majeeji, ati pe mọlẹbi naa ṣe bẹbẹ lati le jẹ ki oun le di eeyan gidi laye paapaa nidi iṣẹ ere agbelewo.

Afeez wi pe “ẹgbẹrun lọna aadọtalenigba naira ti Funmi Martins fun mi ni 1998 si 1999 lẹyin ti mo bawọn ṣe iṣẹ kan ni mo fi bẹre si nii jeeyan laye.

Owo yii ni mo wa kun ti mo fi ṣe sinima akọkọ ti Funmi Martins si kopa nibẹ lai gba kọbọ lọwọ mi.

Owo ti mo si pa ninu ere akọkọ ti mo gbe jade yii ni mo fi bẹrẹ igbesi aye, ti mo si ra ọkọ mi akọkọ.”

Tani Afeez Ọwọ?

Aworan Afeez Owo ati Mide Martins

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mide Martins

Afeez Olayiwola Abiodun, ti gbogbo eyan mọ si Afeez Owo, jẹ oṣere ori itage ati sinima agbelewo, onkọtan, olugbere-jade ati oludari ere.

Wọn bi Afeez ni ọjọ kẹtala oṣu kẹrin ni nkan bii aadọta ọdun sẹyin in ilu Isẹyin nipinlẹ Oyo.

Afeez bẹrẹ sii kopa ninu ere itage lati ile-ẹkọ alakọbẹrẹ nipa ṣiṣe ere fawọn akẹkọjade nibẹ.

Lati lee ṣori-ire laye ni Afeez ṣe gbera kuro nilu Iseyin ni nkan bii 1992 wa sipinlẹ Eko.

Iṣẹ aṣọ-oke hihun ni Afeez fi bẹrẹ nilu Eko ko too di pe o pada di olokiki nidi sinima agbelewo.

Báwo ni ti Mide Martins ṣe jẹ́?

Mide Funmi Martins jẹ oṣere-birin ati olugbere-jade lede Yoruba.

Mide jẹ ọmọ oloogbe Funmi Martins to jẹ gbajugbaja oṣere nigba aye rẹ.

Oke-okun ni Mide wa ko too pada si Naijiria lati waa maa gbe pẹlu iya rẹ.

Lẹyin iku iya rẹ l’ọdun 2002 ni Mide darapọ mọ awọn to n ṣere sinima agbelewo.

Tani Oloogbe Funmi Martins?

Wọn bi Funmi Martins nilu Ileṣa nipinlẹ Osun l’ọdun 1963.

Funmi kawe gboye ‘diploma’ nile-ẹkọ Beepo Secretarial Institute nilu Ibadan.

O ṣe iṣẹ wiwọ aṣọ lati ṣ’oge ko too di ilumọọka nidi ere sinima l’ọdun 1993.

Funmi Martins jẹ ọkan lara awọn oṣere diẹ nigba naa to lee sọ ede Yoruba ati Gẹẹsi ninu sinima.

Oṣu karun ọdun 2002 ni Funmi Martins papo da ni ọmọ ọdun mejindinlogoji.