Ṣé lóòtọ́ ni ọlọ́pàá MOPOL yìnbọn fún ọlọ́kadà l’Osogbo?

Awọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, others

Wahala iwọde ti bẹ silẹ ni ilu Oṣogbo tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ọṣun.

Ohun ti awọn iroyin abẹle ṣalaye pe o fa eyi ni bi wọn ṣe ni awọn ọlọpaa kan yinbọn pa smọdekunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Saheed Ọlabomi ni agbegbe Oke Onitea nilu Oṣogbo.

Iṣẹlẹ naa la gbọ wi pe o ṣẹlẹ ni nnkan bii agogo marun un ọjọ Iṣẹgun ti wọn si ti gbe ọmọkunrin naa lọ si ileewosan nla LAUTECHTH nilu Oṣogbo kan naa.

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ṣalaye pe iṣẹ alupupu gigun ti ọpọ mọ si ọkada ni Ọlabomi n ṣe.

Wọn ni awọn ọlọpaa atawọn awakọ akoyanrin ni wọn n fa wahala ki awọn ọlọpaa to bẹrẹ si nii yinbọn soke lakọlakọ.

Aṣita ibọn ti wọn n yin lakọlakọ naa lo lọ ba Ọlabomi nibi ọrun lori ọkada rẹ.

Ni asiko ti a n ko iroyin yii jọ, gbogbo oju popo lagbegbe naa lawọn ọlọkada atawọn ọdọ ti n fi ẹhonu han ti wọn si n jo taya ọkọ kaakiri awọn agbegbe bii Okefia nilu Osogbo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ