Ṣé lóòtọ́ ni Lobi Stars fẹ́ ra Christiano Ronaldo lẹ́yìn tí òun àti Man United pínyà?

Christiano Ronaldo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ agbabọọlu Lobi Stars ilu Makurdi ti kede pe ko si ohun to jọ pe awọn n mura lati ra Chritiano Ronaldo lẹyin ti adehun rẹ ati Manchester United wa sopin.

Ibẹrẹ ọsẹ ti a wa ni Machester United fopin si adehun rẹ pẹlu Ronaldo lẹyin ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu akọroyin, Piers Morgans.

Ninu ifọwerọ naa ni agbabọọlu ọhun ti sọrọ nipa ohun to n lọ ninu ikọ naa ti inu rẹ ko dun si.

O tun sọrọ nipa akọnimọọgba ikọ naa, Erik Ten Hag, atawọn eeyan mii, amọ awọn ọrọ to jade ninu ifọrọwerọ naa ko dun mọ ikọ ọhun ninu.

A ko tii gbe igbesẹ lati kan si Ronaldo

Lobi Stars FC

Oríṣun àwòrán, @lobistars

Ninu atẹjade kan loju opo Twitter rẹ, ẹgbẹ agbagbọọlu Lobi Stars sọ pe oun ko tii kan si Ronaldo lẹyin ti Man United pinya pẹlu rẹ.

Atẹjade naa ni “A fẹ fi akoko yii sọ fun yin pe a ko tii kan si Cristiano Ronaldo lẹyin ti Manchester United tu silẹ.”

“Adura wa ni pe Ọlọrun yoo ṣe ọna rẹ ni rere, a ko ni sọ ohunkohun lori igbesẹ yii mọ.”

Lati igba ti agbabọọlu naa ati Man U ti pin gari ni oniruru awọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye ti n woye ikọ ti yoo darapọ mọ.

Ronaldo wa lara awọn agbabọọlu to n ṣoju orilẹ-ede Portugal ninu idije ife ẹyẹ agbaye Qatar 2022 to n lọ lọwọ.

Igbagbọ si wa pe yoo mọ igbesẹ to kan fun lẹyin ifẹ ẹyẹ agbaye ọhun.