Ṣé lóòtọ́? Bóo bá ń mu Garri jù tí wọ́n tàn ẹ́ pé ojú dídùn ni yóò gbẹ̀yìn rẹ; gbọ́ òótọ́ lẹ́nu onímọ̀

Awọn ọrọ Yoruba kan wa to kan jẹ jade  lati ọdun pipẹ sẹyin ti ọpọlọpọ si gbagbọ pe bẹẹ lo ri.

Ọpọlọpọ awọn ọrọ yii ni kii ṣe ootọ bẹẹ si ni diẹ lara wọn ṣeeṣe ko jẹ otitọ.

Eyi jẹ jade ninu akanṣe eto BBC Yoruba “Ṣe lootọ ni?” ti a maa n ṣe pẹlu onimọ nipa ilera lori oniruuru awọn akori ọrọ ti nnkankan ṣokunkun si awọn eeyan nipa wọn.

Oriṣiriṣi ohun ti Yoruba n pe ni fabu to rọ mọ oju ni a n gbe yẹwo lonii pẹlu Ọjọgbọn Ositelu lati ileewosan Fasiti ilu Eko.

Ṣe lootọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣe lootọ ni pe ẹni to maa n mu Garri ju yoo ri iṣoro oju didun gbẹyin ni?

Onimọ Ositelu jẹ ko di mimọ pe irọ gbaa ni. O tọka si oriṣiriṣi nnkan ti wọn n fi paki ṣe bayii yatọ fun Garri ti a si n jẹ gbogbo ẹ nitorinaa, Garri nikan ko lee fa oju didun.

“Ẹ lee wa suga ati ẹpa to pọ daadaa gan sii kẹẹ tun fi gbadun Garri yin, ko si oju didun kankan.”

Ọpọlọpọ ọ̀rọ ti awọn eeyan ti gbagbọ pe ootọ ni koda to ti ṣakoba fun ọpọlọpọ ni Ọjọgbọn ba wa sọrọ lorii rẹ ninu fidio to wa loke yii to fi mọ awọn nnkan to jọ mọ aṣa ibilẹ.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí