Ṣé lóòótọ́ ni Ooni lọ ṣe àbẹ̀wò sí Emefiele lọ́gbà ẹ̀wọ̀n?

Aworan Ooni Ogunwusi ati Emefriele

Oríṣun àwòrán, Instagram

Saaju ni iroyin kan gba ori ayelujara pe Ooni ti ilu ile ife, Oba Adeyeye Ogunwusi se abẹwo si Gomina banki apapọ tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Godwin Emefiele ni ọgba ẹwọn Kuje niluu Abuja.

Emefiele ni Ileẹjọ ni ko ma gba atẹgun lọgba ẹwọn lẹyin ti ko ri baali gba lọsẹ to kọja.

Bẹẹ ba gbagbe ninu oṣu kẹjọ ni Ajọ EFCC kọkọ fẹsun kan Emefiele. arábìnrin Saadatu Yaro ati ileeṣẹ April 1616 to jẹ ileeṣẹ arabinrin Yaro lori ẹsun pe wọn ra awọn ọkọ ayọkẹlẹ kan ni ilana to lodi si ofin.

Agbẹnusọ Ooni, Otunba Moses Olafare sọ fun BBC pe ohun iyalẹnu lo jẹ nigba ti oun ri iroyin to n lọ kaakiri pe Ooni ṣe abẹwo si Emefiele.

O sapejuwe iroyin naa gẹgẹ bi iroyin ofege ti ko ni ẹsẹ ni ile rara ati pe ohun ti Ooni lọ se ni ọgba Kuje yatọ ohun ti ọpọ awọn ileeṣẹ iroyin n gbe kiri lori ayelujara.

“Ooni lọ si Kuja nitori awọn eeyan kan pe ransẹ pe awọn fẹ ki wọn si bi eto idanilẹkọ ti gbe kalẹ fun awọn ẹlẹwọn, ki wọn si gba wọn ni imọran.

“Eto jẹ ohun to wa lori ayelujara ti ọpọ n wo, ko ki n se eto inu kọrọ, to si jẹ pe ọpọ awọn akọroyin lo wa ni bi eto yii.

“Ohun to yanilẹnu nigba ti mo ri iroyin naa pe awọn ileeṣẹ iroyin kan ni awọn se iwadi pe Ooni lọ se abẹwọ si Emefiele.

“A ni lati sọra pẹlu bi awọn eeyan se n gbe iroyin ofege kiri nipa eeyan.”

‘Ooni Ife gbọ́dọ̀ tọrọ àforíjì fún pípè àwọn obìnrin ní àjẹ́’

Aworan OONi Ile-Ife

Oríṣun àwòrán, @OoniAdimulaIfe/X

Ẹgbẹ kan ti wọn pe ara wọn ni ‘Advocacy for Alleged Witches’ lo ti kesi Ooni Ile-Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi, lati tọrọ aforiji lọwọ awọn obinrin fun pipe gbogbo obinrin ni ajẹ.

Ẹgbẹ ọhun, ti wọn n ja fẹtọ awọn obinrin ti wọn ba fi ẹsun ajẹ kan, ni adari wọn, Ọmọwe Leo Igwe, tẹnumọ idi ti ọba alaye naa fi gbọdọ tọrọ aforiji ninu atẹjade kan.

Oba Ogunwusi, nigba to gbalejo awọn oṣere ‘The Real Housewives of Lagos’, laafin rẹ lo wi pe “gbogbo obinrin lo mọ ayinike to si tun ayinipada leyi to mu ki awọn kan maa pe wọn lajẹ”.

Awọn ẹgbẹ yii lo waa koro oju si ọrọ ti Ooni sọ yii, ti wọn si wi pe ki o ka ọrọ naa pada ko si tọrọ aforiji lọwọ awọn obinrin.

Ninu atẹjade ọhun, Igwe wi pe awọn obinrin ko ni ọgbọn alumọkọrọyi kankan yala ni ti daadaa abi laburu to lee mu ki wọn maa pe wọn lajẹ.

Lara ohun to wa ninu atẹjade naa ka pe “lakoko ti awọn eeyan n lo gbogbo ọna lati fiyajẹ, ṣe akọlu ati gbẹmi awọn obinrin ti ko ṣẹ, o jẹ ohun ti ko boju mu ki Ooni lo ipo rẹ lati maa mu ki awọn eeyan o korira awọn obinrin ki wọn maa ṣe wọn nika.

“O yẹ ki Ooni mọ pe gbogbo ohun ti oun ba sọ lawọn aye n tẹti gbọ, ko si waa yẹ ko lo ipo rẹ lati fi yẹpẹrẹ awọn obinrin abi ẹnikẹni.

“Ọrọ to sọ lo wuwo to si lee lapa lori bi awọn eeyan ṣe n wo obinrin ati irufẹ iwa ti wọn yoo hu si wọn.

“O yẹ ki Ooni o mọ pe ohun ko le maa sọ iru awọn awọn yii, nitori naa, ki o tọrọ aforiji lọwọ awọn obinrin ko si gba ọrọ naa pada.

“Ẹgbẹ wa n kede rẹ pe ko si obinrin to ni ajẹ rere abi buburu lati fi dari awọn eniyan si daadaa abi idakeji rẹ. Igbagbọ ti ko fẹsẹmulẹ ni igbagbọ ninu ajẹ. O si yẹ ki Ooni waa ro tawọn obinrin nminu gbogbo ọrọ rẹ.”