Ǹkan dé o! Àwọn jàndùkú tún yìnbọn pa ọlọ́pàá méje lẹ́nu iṣẹ́, wọ́n dáná sun ọkọ̀ wọn

Awọn ọlọpaa Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn janduku agbebọn tun ti yinbọn pa awọn ọlọpaa mẹfa lẹnu iṣẹ wọn nipinlẹ Rivers lalẹ ọjọ Ẹti, ọjọ keje oṣu karun ọdun 2021.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers, SP Nnamdi Omoni fi sita, o ni bi ago mẹjọ abọ alẹ ni iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.

O ṣalaye ninu atẹjade naa pe ọkọ Hilux lawọn agbebọn naa fi ṣe iṣẹ laabi ti wọn ṣe lọjọ Ẹti.

Awọn ọlọpaa to wa lori afara Choba lawọn agbebọn naa kọkọ kọlu nibi ti wọn ti pa ọlọpaa meji ti wọn si tun dana sun ọkọ ọkan lara awọn ọlọpaa ọhun.

Awọn agbebọn naa tun gbera lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Rumuji nibi ti wọn tun ti pa ọlọpaa meji mi ti wọn si tun dana sun ọkọ awọn ọlọpaa.

Nnamdi sọ ninu atẹjade naa pe awọn agbofinro naa kọju ija sawọn agbebọn ọhun nigba ti wọn de eyi to mi ki meji lara wọn gbẹmi mi.

Ọkọ awọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Rivers State Police

Bakan naa ni wọn tun kọlu agọ ọlọpaa to wa ni Elimgbu, bo tilẹ jẹ pe wọn ba awọn ọlọpaa naa nile.

Awọn ọlọpaa kọju ija sawọn janduku agbebọn ọhun, ṣugbọn mẹta ninu awọn ọlọpaa lo ba iṣẹlẹ naa lọ.

Awọn agbebọn naa ko ri ọkọ Hilux ti wọn gbe wa pada gbe lọ, ọkọ Sienna ti wọn ji gba lọwọ ẹnikan ni wọn gbe lọ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn agbebọn naa fara gbọta yana yana eyi to da apa si wọn lara.

Ọkọ awọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Rivers State Police

Wọn tun gbe Sienna naa silẹ nigba tawọn ọlọpaa ko pada lẹyin wọn, bayii ni wọn ṣe na papa bora pẹlu apa ọta ibọn lara wọn.

Ẹwẹ, wọn ti gbe oku awọn ọlọpaa to ṣubu loju ogun lọ si mọsuari, nigbati ọga ọlọpaa ipinlẹ Rivers, Eboka Friday sẹleri pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo ṣe awari awọn kọlọnbiti ẹda naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa wa rọ awọn araalu lati fi to awọn ọlọpaa leti ti wọn ba ri ẹnikẹni pẹlu apa ibọn lara wọn.