Ǹ jẹ́ àwọn oúnjẹ tí a pò pọ̀ mọ́ kẹ́míkà dára fún àgó ara?

Aworan ounjẹ to le wa fun igba pipẹ nitori nnkan ti wọn ti po pọ mọ.

Awọn ounjẹ inu agolo ni wọn ti kede pe o ni asopọ pẹlu orisirisi aisan to le ni ọgbọn bi aisan ọkan, jẹjẹrẹ ati ai farabalẹ.

Iwadi ile-ẹkọ giga fasiti tuntun kan sọ pe ounjẹ inu agolo yii le ṣe ijamba fun ilera eeyan.

Awọn ounjẹ ti a ṣe sinu agolo naa lo gbajumọ nilẹ Amẹrika ati UK, awọn ounjẹ bẹẹ si ti n di olokiki kaakiri agbaye.

Ki a n pe ni ounjẹ inu agolo?

Ko si itumọ kan bayii ti a le fun awọn ounjẹ inu agolo sugbọn awọn ohun ti wọn fi pelo rẹ ni kii ṣe awọn ohun ti a fi dana ni ile.

Pupọ wọn lo jẹ kẹmika, ati awọn ohun adidun ti wọn ko sinu ounjẹ naa lo n jẹ ko dun lẹnu ati loju.

Awọn ohun mimu bii ‘fizzy’, adun ati adiyẹ dindin ‘chicken nuggets’ jẹ apẹẹrẹ.

Sibẹsibẹ, wọn tun le fiwọn sinu awọn ounjẹ bi burẹdi, awọn ounjẹ owurọ ati miliki.

Ki ni iyatọ laarin ounjẹ inu agolo ati ounjẹ atawọda?

Lati le ṣe iranlọwọ fun awọn eeyan lati da awọn ounjẹ yii mọ, wọn pin awọn ounjẹ yii si isọri mẹrin.

 • Awọn ounjẹ ti wọn ko tọwọbọ tabi po nnkan pọ pẹlu wọn
 • Awọn ounjẹ ti wọn tọwọbọ diẹ
 • Awọn eroja ti wọn ti po nnkan pọ pẹlu wọn
 • Awọn ounjẹ atọwọda ati awọn ounjẹ inu agolo ti wọn tọwọbọ
Aworan

Awọn ounjẹ ti wọn ti tọwọbọ ni a le pe ni ounjẹ ti wọn po ọpọlọpọ ounjẹ mii pọ bii eso, ẹfọ ati ẹyin ati awọn eroja mii ti wọn ti po pọ.

Fun apẹẹrẹ, burẹdi ti wọn se pẹlu fulawa wiiti, iyọ ati ororo jẹ ounjẹ ti a po pọ.

Ẹwẹ, ti a ba ti n ṣafikun si awọn ounjẹ ti a po pọ yii, ti wọn n fi eroja ti yoo yi awọ rẹ pada tabi ti ko jẹ ko tete bajẹ, o ti di ounjẹ ti a po kẹmika pọ mọ.

Bawo lo ṣe le mọ ounjẹ ti wọn po nnkan pọ mọ?

Awọn ounjẹ to wa ninu agolo ti wọn ba ti ni eroja to le ni marun un ni o ṣeeṣe ko jẹ ounjẹ ti wọn ti po nnkan pọ mọ gẹgẹ bii onimọ nipa eto ilera, Ọjọgbọn Maira Bes-Rastrollo ti fasiti Navarra lorilẹede Spain se sọ.

Awọn ounjẹ ti wọn ti po nnkan pọ mọ yii ni wọn ma n kun fun iyọ, ṣuga ati ọpọlọpọ ọra

Ni UK ati ni awọn orilẹede mii, awọn eroja yii ni yoo wa lara ounjẹ inu agolo ti ẹ ba ra.

O le jẹ ounjẹ ti wọn sẹsẹ ṣe sugbọn, o le wa fun igba pipẹ nitori awọn nnkan ti wọn ti po pọ mọ wọn.

Ri daaju pe o yẹ awọn nnkan ti wọn kọ si lara wo lati ri awọn eroja bii sodium benzoate, nitrate ati sulphite, BHA ati BHT ninu rẹ.

Bawo ni awọn ounjẹ ti wọn po nnkan pọ mọ ṣe tan kaakiri agbaye ?

Awọn eeyan ni ilẹ Gẹẹsi ati Amẹrika ni wọn jẹ ọpọ awọn ounjẹ ti wọn ti po nnkan pọ mọ, gẹgẹ bii ajọ British Medical Journal ati US Medical Center fun iroyin nipa Biotechnology ṣe ṣalaye.

Ni ọdun 2023, ida 58% ni apapọ awọn agbalagba to n jẹ ounjẹ yii ni US, ti ida 66% ninu wọn si jẹ ti ọmọde.

Awọn ida yii jẹ ida 57% ati 65% fun awọn agbalagba ati awọn ọmọde UK.

Aworan

Ileeṣẹ ilera orilẹede Amẹrika sọ pe ni awọn orilẹede Asia bii South Korea ati Japan, ati ni awọn orilẹede South America biI Brazil ati Chile, awọn ounjẹ yii ni ohun iṣara loore ida 20 – 30%.

Ni South Africa, nọmba yii jẹ 39%.

N jẹ jijẹ awọn ounjẹ yii le ṣakoba fun ilera rẹ?

Ko si ẹri kankan nipa ipalara ti ounjẹ yii le se fun ilera ara.

Iwadi kan to jade ninu oṣu keji ọdun 2024 ni Ileeṣẹ to n ri si ilera nilẹ Gẹẹsi sọ pe – gẹgẹ bi ohun ta ri gbọ lati ọwọ awọn eeyan toto miliọnu mẹsan an kari agbaaye ni- awọn ounjẹ yii sopọ mọ:

 • Isanraju
 • Oriṣi aisan atọgbẹ meji
 • Iṣoro orun sisun
 • Nini rẹwẹsi ọkan

Ẹwẹ, iwadi naa ko le fi idi rẹ mulẹ pe jijẹ ounjẹ yii lo fa awọn aisan naa.

O le jẹ nitori awọn ounjẹ naa ni ọpọlọpọ ọra, suga ati iyọ, eyiti o nmu ki awọn eeyan lomi lara si iru aisan atọgbẹ , aisan ọkan ati diẹ ninu awọn aarun jẹjẹrẹ.

“Ẹri akọkọ pe eeyan n jẹ awọn ounjẹ ti wọn po mọ nnkan ni ara sisan,” Chris van Tulleken, onimọ-jinlẹ lati ile iwosan Ile-ẹkọ fasitii ti London, ti o tun ti kọ nipa ounjẹ to n se ara loore.

“Awọn ounjẹ wọnyi ni wọn ni ọpọlọpọ ọra, iyọ ati suga lara. Ṣugbọn bi wọn pelo wọn – nipasẹ awọn awọn eroja alawọ ati awọn adun – to jẹ pe wọn gbọdọ jẹ ọpọlọpọ rẹ.”

Iwadii oṣu keji ọdun 2024 lati ọwọ Imperial College London sọ pe ni ọdun 2022, o le ni bilionu kan eeyan ni agbaye ni yoo ma gbe pẹlu ara sisan.

O sọ pe laarin ọdun 1992 si 2022, ara sisan jẹ ilọpo meji fun fun awọn obinrin agbalagba, ilọpo mẹta fun awọn ọkunrin agbalagba, ati ilọpo marun u fun awọn ọmọde ati awọn ọdọ.

Awọn iwadii to jade lati ọwọ Ajo Ilera Agbaye (WHO) ati Alabojuto Ilera Agbaye, lati ọdun 2016, sọ pe o le ni ida 28% awọn agbalagba ni Amẹrika ti wọn sanra, ida 26% ni Europe, ida 19% ni Ila-oorun Mẹditarenia ati ida 9 % ni Afirika.

Aworan

Ni ọdun 2016, WHO sọ pe, eeyan to din diẹ ni bilọnu mẹta ni wọn padanuẹmi wọn ọlọdọdun nitori pe wọn sanra.

“Ni ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede ni agbaye, ounjẹ ti a ṣe ilana to la pipo nnkan mi pọ mọ ni o jẹ ohun ti ko kọja agbara, ti ẹ si le ri nibi kibi ju awọn ounjẹ ibilẹ lọ ninu ọja,” Dokita Claire Johnson, onimọ niap ounje ni ile-iṣẹ UN fun awọn ọmọde, Unicef sọ.

Aarun Atọgbẹ

Ọpọ awọn eeyan ni agbaye bayii lo ni ipin keji aarun atọgbẹ gẹgẹ bii ajọ International Diabetes Federation ṣe ṣalaye.

Jaakko Tammilehto, Ọjọgbọn nipa ilera gbogbogbo ni ile-ẹkọ giga ti Helsinki sọ pe “Suga, iyọ ati ọra ninu ounjẹ ti a ṣe ilana pipo nnkan pọ jẹ okunfa eewu fun idagbasoke iru àtọgbẹ.

Aarin ila-oorun Middle East ati Ariwa Afirika ti rii ilọsoke ni iye awọn eeyan to ni aarun àtọgbẹ 2.

“Ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede yii ni ko ki n pese ounjẹ fun ara wọn,” Ọjọgbọn Tammilehto lo sọ bẹẹ.

“Ounjẹ ti a ṣe ni ilana pipo nnkan pọ yii rọrun lati gbe rin irinajo ati lati fi pamọ.

“Eyi ni ohun ti awọn ile-iṣẹ ounjẹ n fi ranṣẹ julọ.”

Aijẹ ounjẹ asara loore

Ounjẹ ti a ṣe ni ilana pipọ nnkan mii pọ mọ yii n sokunfa ọpọlọpọ awọn ohun ti ko ki n ṣe ara loore ni ọpọlọpọ awọn orilẹede Afrika, Dokita Johnson lo sọ bẹẹ.

Ẹwẹ, awọn onimo ijinlẹ sayẹnsi ni Ile-ẹkọ giga Fasiti Purdue ni nilẹ Amẹrika sọ pe awọn ounjẹ yii le ni awọn anfanibii:

 • Pipese awọn eroja gẹgẹ bii Vitamin E ati kaṣiọmu.
 • Pipese ounjẹ bii ounjẹ ibilẹ fun awọn eeyan ti owo wọn ko pọ
 • Mimu adinku ba bi ounjẹ se n sofo ati ewu jijẹ majele ninu ounjẹ

Ileeṣẹ ijọba British Nutrition Foundation ṣe afihan pe kii ṣe gbogbo awọn ounjẹ yii lo jẹ nnkan naa.

O ni “Awọn ounjẹ ti a le pin si isọri ilana yii, bi awọn ounjẹ owurọ bii burẹdi ni o le ma ni ọpọlọpọ ọra, iyọ ati suga ninu wọn.”

Arun ọkan

Iwadi oṣu Kẹfa, ọdun 2024 kan lati Ile-ẹkọ giga fasiti Sao Paolo ati Ile-ẹkọ giga Imperial College niluu London gba imọran pe awọn nnkan ọgbin ti wọn ti po nnkan pọ mọ le ṣe akoba fun ilera nitori o lewu pupọ.

Iwadii naa tẹsiwaju pe awọn ounjẹ ti wọn po nnkan pọ mọ ki wọn to gbin wọn gbin ni ajọsepọ pẹlu ida meje ohun to n sokunfa aisan bi aisan ọkan ati arun rọpa rọsẹ dipo jijẹ eyi ti wọn ko po nnkan pọ mọ.

Ki ni awọn igbesẹ ti wọn ti gbe tako jijẹ awọn ounjẹ ti wọn po nnkan pọ mọ?

Ijọba UK ti fi owo-ori kan sori awọn ohun mimu to ni ṣuga ninu lọdun 2018, eyii to mu ki ọpọlọpọ awọn ileeṣẹ din suga wọn ku.

Lọdun 2023, Columbia paṣẹ owo-ori ida mẹwaa – eyi to tun lekun si bi ọjọ se n gun ori ọjọ – lori awọn ohun mimu suga ati awọn ounjẹ yii.

Lọdun 2016, Chile – ibi ti ọpọ awọn ọmọde ti sanra julọ lagbaye – fi ikilọ sara awọn ohun tita to ni suga, ọra tabi kalori.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba tun ti fofin de ipolowo ounjẹ ọmọde to ni ọpọlọpọ suga ati iyọ ninu.

Ẹwe, ni awọn ọdun mẹrin lẹyin awọn igbese yii , oṣuwọn awọn ọmọde to n sanra lawọn orilẹede naa tesiwaju lati maa pọ si.